Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là, Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu. Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa.

Jeremiah 23:6 in English

Jeremiah 23:6 · Berean Standard Bible

In His days Judah will be saved, and Israel will dwell securely. And this is His name by which He will be called: The LORD Our Righteousness.*

Context

4Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí. 5“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà. 6Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là, Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu. Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa. 7Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’ 8Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú-ọmọ ilé Israẹli wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.