Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?

Jeremiah 23:18 in English

Jeremiah 23:18 · Berean Standard Bible

But which of them has stood in the council of the LORD to see and hear His word? Who has given heed to His word and obeyed it?

Context

16Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu Olúwa. 17Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’ 18Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà? 19Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú. 20Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀ títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ, ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.