Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’

Jeremiah 23:17 in English

Jeremiah 23:17 · Berean Standard Bible

They keep saying to those who despise Me, ‘The LORD says that you will have peace,’ and to everyone who walks in the stubbornness of his own heart, ‘No harm will come to you.’

Context

15Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.” 16Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu Olúwa. 17Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’ 18Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà? 19Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.