Jeremiah 23:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”
Jeremiah 23:15 in English
Jeremiah 23:15 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the LORD of Hosts says concerning the prophets: “I will feed them wormwood and give them poisoned water to drink, for from the prophets of Jerusalem ungodliness has spread throughout the land.”
Context
13“Láàrín àwọn wòlíì Samaria,
Èmi rí ohun tí ń lé ni sá.
Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali
wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà. 14Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu,
èmi ti rí ohun búburú.
Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké.
Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára,
tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.
Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi,
àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.” 15Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì:
“Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò,
wọn yóò mu omi májèlé
nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu
ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.” 16Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín.
Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán.
Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn,
kì í ṣe láti ẹnu Olúwa. 17Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé,
‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’
Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé,
‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.