Jeremiah 22:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀, wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀, wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.
Jeremiah 22:7 in English
Jeremiah 22:7 · Berean Standard Bible
I will appoint destroyers against you, each man with his weapons, and they will cut down the choicest of your cedars and throw them into the fire.
Context
5Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ” 6Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda,
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi,
gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni,
dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,
àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn. 7Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ,
olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,
wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀,
wọn ó sì kó wọn jù sínú iná. 8“Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’ 9Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.