Jeremiah 22:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.
Jeremiah 22:6 in English
Jeremiah 22:6 · Berean Standard Bible
For this is what the LORD says concerning the house of the king of Judah: “You are like Gilead to Me, like the summit of Lebanon; but I will surely turn you into a desert, like cities that are uninhabited.
Context
4Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 5Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ” 6Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda,
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi,
gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni,
dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,
àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn. 7Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ,
olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,
wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀,
wọn ó sì kó wọn jù sínú iná. 8“Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.