Jeremiah 21:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
Jeremiah 21:11 in English
Jeremiah 21:11 · Berean Standard Bible
Moreover, tell the house of the king of Judah to hear the word of the LORD.
Context
9Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Babeli tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. 10Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’ 11“Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 12Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ:
“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀;
yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára
ẹni tí a ti jà lólè
bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná.
Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó
láìsí ẹni tí yóò pa á. 13Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jerusalẹmu,
ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì
lórí òkúta tí ó tẹ́jú, ni Olúwa wí.
Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojúkọ wá?
Ta ni yóò wọ inú ibùgbé wa?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.