Jeremiah 21:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ: “ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀; yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára ẹni tí a ti jà lólè bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná. Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó láìsí ẹni tí yóò pa á.
Jeremiah 21:12 in English
Jeremiah 21:12 · Berean Standard Bible
O house of David, this is what the LORD says: ‘Administer justice every morning, and rescue the victim of robbery from the hand of his oppressor, or My wrath will go forth like fire and burn with no one to extinguish it because of their evil deeds.
Context
10Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’ 11“Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 12Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ:
“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀;
yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára
ẹni tí a ti jà lólè
bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná.
Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó
láìsí ẹni tí yóò pa á. 13Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jerusalẹmu,
ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì
lórí òkúta tí ó tẹ́jú, ni Olúwa wí.
Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojúkọ wá?
Ta ni yóò wọ inú ibùgbé wa?” 14Èmi yóò jẹ ọ ní ìyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
ni Olúwa wí.
Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀;
yóò si jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.