Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi, agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.

Jeremiah 20:9 in English

Jeremiah 20:9 · Berean Standard Bible

If I say, “I will not mention Him or speak any more in His name,” His message becomes a fire burning in my heart, shut up in my bones, and I become weary of holding it in, and I cannot prevail.

Context

7Olúwa, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà. 8Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà. 9Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi, agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é. 10Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo. Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.” 11Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù. Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀. Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.