Jeremiah 20:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
Jeremiah 20:7 in English
Jeremiah 20:7 · Berean Standard Bible
You have deceived me, O LORD, and I was deceived. You have overcome me and prevailed. I am a laughingstock all day long; everyone mocks me.
Context
5Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli. 6Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.” 7Olúwa, o tàn mí jẹ́,
o sì ṣẹ́gun.
Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,
gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà. 8Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta
èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù
àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà. 9Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ
tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi
nínú egungun mi,
agara dá mi ní inú mi
nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.