Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí. Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.

Jeremiah 2:30 in English

Jeremiah 2:30 · Berean Standard Bible

“I have struck your sons in vain; they accepted no discipline. Your own sword has devoured your prophets like a voracious lion.”

Context

28Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà? Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda. 29“Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí? Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,” ni Olúwa wí. 30“Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí. Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù. 31“Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa: “Mo ha ti di aginjù sí Israẹli tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri? Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri; àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’ 32Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.