Jeremiah 2:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà? Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.
Jeremiah 2:28 in English
Jeremiah 2:28 · Berean Standard Bible
But where are the gods you made for yourselves? Let them rise up in your time of trouble and save you if they can; for your gods are as numerous as your cities, O Judah.
Context
26“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—
àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,
àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú. 27Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’
àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’
wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,
wọn kò kọ ojú sí mi
síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,
wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’ 28Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà?
Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín
nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro!
Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda. 29“Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?
Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”
ni Olúwa wí. 30“Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín,
wọn kò sì gba ìbáwí.
Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run,
gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.