Jeremiah 2:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti láti lọ mu omi ní Ṣihori? Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
Jeremiah 2:18 in English
Jeremiah 2:18 · Berean Standard Bible
Now what will you gain on your way to Egypt to drink the waters of the Nile *? What will you gain on your way to Assyria to drink the waters of the Euphrates *?
Context
16Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi
wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ. 17Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín
nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀
nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà? 18Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti
láti lọ mu omi ní Ṣihori?
Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria
láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà? 19Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín
ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí
mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti
ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ
nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,
ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 20“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù,
ìwọ sì já ìdè rẹ;
ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’
Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni
àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀
ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.