Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

Jeremiah 17:8 in English

Jeremiah 17:8 · Berean Standard Bible

He is like a tree planted by the waters that sends out its roots toward the stream. It does not fear when the heat comes, and its leaves are always green. It does not worry in a year of drought, nor does it cease to produce fruit.

Context

6Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá, kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé, yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù, ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé. 7“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. 8Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.” 9Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè wòsàn. Ta ni èyí lè yé? 10“Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èrò inú ọmọ ènìyàn, láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.