Jeremiah 17:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.
Jeremiah 17:7 in English
Jeremiah 17:7 · Berean Standard Bible
But blessed is the man who trusts in the LORD, whose confidence is in Him.
Context
5Báyìí ni Olúwa wí:
“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,
tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,
àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. 6Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,
kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,
yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,
ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé. 7“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin
náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi
Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. 8Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò
tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò
kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,
gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù
kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá
bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.” 9Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,
ó kọjá ohun tí a lè wòsàn.
Ta ni èyí lè yé?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.