Jeremiah 17:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga.
Jeremiah 17:2 in English
Jeremiah 17:2 · Berean Standard Bible
Even their children remember their altars and Asherah poles by the green trees and on the high hills.
Context
1“Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,
èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,
sórí wàláà oókan àyà wọn,
àti sórí ìwo pẹpẹ yín. 2Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ
àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ
àti àwọn òkè gíga. 3Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀
àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ
pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó
pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín. 4Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin
yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.
Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú
ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀,
nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi,
èyí tí yóò sì wà títí ayé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.