Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù. Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀, nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

Jeremiah 17:4 in English

Jeremiah 17:4 · Berean Standard Bible

And you yourself will relinquish the inheritance that I gave you. I will enslave you to your enemies in a land that you do not know, for you have kindled My anger; it will burn forever.”

Context

2Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga. 3Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀ àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín. 4Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù. Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀, nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.” 5Báyìí ni Olúwa wí: “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. 6Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá, kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé, yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù, ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.