Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli; gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì. Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa, orísun omi ìyè sílẹ̀.

Jeremiah 17:13 in English

Jeremiah 17:13 · Berean Standard Bible

O LORD, the hope of Israel, all who abandon You will be put to shame. All who turn away will be written in the dust, for they have abandoned the LORD, the fountain of living water.

Context

11Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè. 12Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ibi ilé mímọ́ wa. 13Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli; gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì. Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa, orísun omi ìyè sílẹ̀. 14Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi. 15Wọ́n sọ fún mi wí pé: “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà? Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.” Ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.