Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

Jeremiah 17:11 in English

Jeremiah 17:11 · Berean Standard Bible

Like a partridge hatching eggs it did not lay is the man who makes a fortune unjustly. In the middle of his days his riches will desert him, and in the end he will be the fool.”

Context

9Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè wòsàn. Ta ni èyí lè yé? 10“Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èrò inú ọmọ ènìyàn, láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” 11Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè. 12Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ibi ilé mímọ́ wa. 13Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli; gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì. Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa, orísun omi ìyè sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.