Jeremiah 14:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa; má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀. Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á.
Jeremiah 14:21 in English
Jeremiah 14:21 · Berean Standard Bible
For the sake of Your name do not despise us; do not disgrace Your glorious throne. Remember Your covenant with us; do not break it.
Context
19Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
ìpayà là ń rí. 20Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ. 21Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;
má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.
Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá
kí o má ṣe dà á. 22Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?
Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí?
Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.
Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,
nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.