Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

Jeremiah 14:20 in English

Jeremiah 14:20 · Berean Standard Bible

We acknowledge our wickedness, O LORD, the guilt of our fathers; indeed, we have sinned against You.

Context

18Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ” 19Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé o ti ṣá Sioni tì? Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn? A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpayà là ń rí. 20Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ. 21Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa; má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀. Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á. 22Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀? Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí? Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa. Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.