Jeremiah 14:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”
Jeremiah 14:18 in English
Jeremiah 14:18 · Berean Standard Bible
If I go out to the country, I see those slain by the sword; if I enter the city, I see those ravaged by famine! For both prophet and priest travel to a land they do not know.’”
Context
16Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 17“Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:
“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé
ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;
nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,
ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá
pẹ̀lú lílù bolẹ̀. 18Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,
Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.
Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,
èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.
Wòlíì àti Àlùfáà
ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ” 19Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
ìpayà là ń rí. 20Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.