Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Juda, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jerusalẹmu.

Jeremiah 11:2 in English

Jeremiah 11:2 · Berean Standard Bible

“Listen to the words of this covenant and tell them to the men of Judah and the residents of Jerusalem.

Context

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá: 2“Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Juda, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jerusalẹmu. 3Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́. 4Àwọn májẹ̀mú tí mo pàṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Ejibiti, láti inú iná alágbẹ̀dẹ wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi, Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.