Jeremiah 10:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì.
Jeremiah 10:17 in English
Jeremiah 10:17 · Berean Standard Bible
Gather up your belongings from this land, you who live under siege.
Context
15Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà;
nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé. 16Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí,
nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo
àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀.
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 17Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀
ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì. 18Nítorí èyí ni Olúwa wí:
“Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn
àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde.
Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn,
kí wọn kí ó lè rí wọn mú.” 19Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!
Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn,
bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi,
“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.