Jeremiah 1:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ.
Jeremiah 1:9 in English
Jeremiah 1:9 · Berean Standard Bible
Then the LORD reached out His hand, touched my mouth, and said to me: “Behold, I have put My words in your mouth.
Context
7Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” 8Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́. 9Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ. 10Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn. 11Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?”
Mo sì dáhùn wí pé, “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.