Onidajọ 5:9
Judges 5:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn. Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!
Judges 5:9 in English
Judges 5:9 · Berean Standard Bible
My heart is with the princes of Israel, with the volunteers among the people. Bless the LORD!
Context
7Àwọn olórí tán ní Israẹli,
wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde
bí ìyá ní Israẹli. 8Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun,
nígbà náà ni ogun wà ní ibodè
a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan
láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí. 9Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli
àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn.
Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa! 10“Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,
ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára,
àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà.
Ní ọ̀nà jíjìn sí 11ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.
Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa,
àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli.
“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa
sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.