Native Bible

Judges 5:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun, nígbà náà ni ogun wà ní ibodè a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí.

Judges 5:8 in English

Judges 5:8 · Berean Standard Bible

When they chose new gods, then war came to their gates. Not a shield or spear was found among forty thousand in Israel.

Context

6“Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá; àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀. 7Àwọn olórí tán ní Israẹli, wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde bí ìyá ní Israẹli. 8Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun, nígbà náà ni ogun wà ní ibodè a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí. 9Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn. Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa! 10“Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára, àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà. Ní ọ̀nà jíjìn sí

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.