Onidajọ 5:6
Judges 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá; àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀.
Judges 5:6 in English
Judges 5:6 · Berean Standard Bible
In the days of Shamgar son of Anath, in the days of Jael, the highways were deserted and the travelers took the byways.
Context
4“Olúwa nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri,
nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu,
ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀,
àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀. 5Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú Olúwa
Ọlọ́run Israẹli. 6“Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati,
ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá;
àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀. 7Àwọn olórí tán ní Israẹli,
wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde
bí ìyá ní Israẹli. 8Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun,
nígbà náà ni ogun wà ní ibodè
a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan
láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.