Native Bible

Judges 5:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá.

Judges 5:18 in English

Judges 5:18 · Berean Standard Bible

Zebulun was a people who risked their lives; Naphtali, too, on the heights of the battlefield.

Context

16Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn? Ní ipadò Reubeni ni ìgbèrò púpọ̀ wà. 17Gileadi dúró ní òkè odò Jordani. Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi? Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun, ó sì ń gbé èbúté rẹ̀. 18Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá. 19“Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà; àwọn ọba Kenaani jà ní Taanaki ní etí odo Megido, ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó. 20Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.