Onidajọ 5:16
Judges 5:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn? Ní ipadò Reubeni ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
Judges 5:16 in English
Judges 5:16 · Berean Standard Bible
Why did you sit among the sheepfolds to hear the whistling for the flocks? In the clans of Reuben there was great indecision.
Context
14Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki;
Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.
Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá,
láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́. 15Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora;
bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki,
wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.
Ní ipadò Reubeni
ni ìgbèrò púpọ̀ wà. 16Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn
láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn?
Ní ipadò Reubeni
ni ìgbèrò púpọ̀ wà. 17Gileadi dúró ní òkè odò Jordani.
Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi?
Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun,
ó sì ń gbé èbúté rẹ̀. 18Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;
bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.