Onidajọ 18:19
Judges 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?”
Judges 18:19 in English
Judges 18:19 · Berean Standard Bible
“Be quiet,” they told him. “Put your hand over your mouth and come with us and be a father and a priest to us. Is it better for you to be a priest for the house of one person or a priest for a tribe and family in Israel?”
Context
17Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà. 18Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?” 19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?” 20Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ. 21Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.