Native Bible

Judges 18:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà.

Judges 18:17 in English

Judges 18:17 · Berean Standard Bible

And the five men who had gone to spy out the land went inside and took the graven image, the ephod, the household idols, and the molten idol, while the priest stood at the entrance of the gate with the six hundred armed men.

Context

15Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà, sí ilé Mika, wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀. 16Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dani náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi. 17Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà. 18Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?” 19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.