Native Bible

Judges 18:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.

Judges 18:21 in English

Judges 18:21 · Berean Standard Bible

Putting their small children, their livestock, and their possessions in front of them, they turned and departed.

Context

19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?” 20Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ. 21Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ. 22Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Mika, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè Mika kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá. 23Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dani yípadà wọ́n sì bi Mika pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.