Onidajọ 15:16
Judges 15:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Samsoni sì wí pé, “Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, mo ti pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin.”
Judges 15:16 in English
Judges 15:16 · Berean Standard Bible
Then Samson said: “With the jawbone of a donkey I have piled them into heaps.* With the jawbone of a donkey I have slain a thousand men.”
Context
14Bí ó ti súnmọ́ Lehi, àwọn Filistini ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. 15Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tuntun kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin. 16Samsoni sì wí pé,
“Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan,
mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan,
mo ti pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin.” 17Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Lehi (ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ pa). 18Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe Olúwa, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.