Native Bible

Judges 14:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó.

Judges 14:12 in English

Judges 14:12 · Berean Standard Bible

“Let me tell you a riddle,” Samson said to them. “If you can solve it for me within the seven days of the feast, I will give you thirty linen garments and thirty sets of clothes.

Context

10Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Samsoni sì ṣe àsè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà. 11Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́. 12Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. 13Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.” Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.” 14Ó dáhùn pé, “Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá; láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.” Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.