Onidajọ 14:13
Judges 14:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.” Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.”
Judges 14:13 in English
Judges 14:13 · Berean Standard Bible
But if you cannot solve it, you must give me thirty linen garments and thirty sets of clothes.” “Tell us your riddle,” they replied. “Let us hear it.”
Context
11Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́. 12Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. 13Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”
Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.” 14Ó dáhùn pé,
“Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá;
láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.”
Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà. 15Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Samsoni, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòṣì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.