Onidajọ 14:11
Judges 14:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́.
Judges 14:11 in English
Judges 14:11 · Berean Standard Bible
And when the Philistines saw him,* they selected thirty men to accompany him.
Context
9ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà. 10Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Samsoni sì ṣe àsè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà. 11Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́. 12Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. 13Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”
Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.