Isaiah 9:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu; yóò sì wá sórí Israẹli.
Isaiah 9:8 in English
Isaiah 9:8 · Berean Standard Bible
The Lord has sent a message against Jacob, and it has fallen upon Israel.
Context
6Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fi ọmọkùnrin kan fún wa,
ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.
A ó sì máa pè é ní
Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára,
Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà. 7Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni yóò mú èyí ṣẹ. 8Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
yóò sì wá sórí Israẹli. 9Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—
tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga
àti gààrù àyà pé. 10Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,
a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀
ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.