Isaiah 8:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Di májẹ̀mú náà kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.
Isaiah 8:16 in English
Isaiah 8:16 · Berean Standard Bible
Bind up the testimony and seal the law among my disciples.
Context
14Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́
ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀
àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú
àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn. 15Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀,
wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,
okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.” 16Di májẹ̀mú náà
kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi. 17Èmi yóò dúró de Olúwa,
ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu.
Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ. 18Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òkè Sioni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.