Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò dúró de Olúwa, ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu. Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.

Isaiah 8:17 in English

Isaiah 8:17 · Berean Standard Bible

I will wait for the LORD, who is hiding His face from the house of Jacob. I will put my trust in Him.*

Context

15Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀, wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá, okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.” 16Di májẹ̀mú náà kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi. 17Èmi yóò dúró de Olúwa, ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu. Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ. 18Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òkè Sioni. 19Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.