Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Isaiah 66:14 in English

Isaiah 66:14 · Berean Standard Bible

When you see, you will rejoice, and you will flourish like grass; then the hand of the LORD will be revealed to His servants, but His wrath will be shown to His enemies.

Context

12Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀. 13Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.” 14Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. 15Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle; òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú, àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná. 16Nítorí pẹ̀lú iná àti idà ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.