Isaiah 66:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pẹ̀lú iná àti idà ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.
Isaiah 66:16 in English
Isaiah 66:16 · Berean Standard Bible
For by fire and by His sword, the LORD will execute judgment on all flesh, and many will be slain by the LORD.
Context
14Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn
ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;
ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. 15Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná
àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;
òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,
àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná. 16Nítorí pẹ̀lú iná àti idà
ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa. 17“Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí. 18“Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.