Isaiah 60:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé. Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọláńlá mi hàn.
Isaiah 60:21 in English
Isaiah 60:21 · Berean Standard Bible
Then all your people will be righteous; they will possess the land forever; they are the branch of My planting, the work of My hands, so that I may be glorified.
Context
19Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,
tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,
nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,
àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ. 20Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,
àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;
Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,
àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin. 21Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo
àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.
Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,
iṣẹ́ ọwọ́ mi,
láti fi ọláńlá mi hàn. 22Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún (1,000) kan,
èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.
Èmi ni Olúwa;
ní àkókò rẹ̀, Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.