Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

Isaiah 60:20 in English

Isaiah 60:20 · Berean Standard Bible

Your sun will no longer set, and your moon will not wane; for the LORD will be your everlasting light, and the days of your sorrow will cease.

Context

18A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́, tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn. 19Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ. 20Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin. 21Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé. Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọláńlá mi hàn. 22Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún (1,000) kan, èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá. Èmi ni Olúwa; ní àkókò rẹ̀, Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.