Isaiah 60:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.
Isaiah 60:19 in English
Isaiah 60:19 · Berean Standard Bible
No longer will the sun be your light by day, nor the brightness of the moon shine on your night;* for the LORD will be your everlasting light, and your God will be your splendor.*
Context
17Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,
dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,
àti irin dípò òkúta.
Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ
àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ. 18A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,
tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,
ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà
àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn. 19Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,
tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,
nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,
àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ. 20Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,
àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;
Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,
àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin. 21Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo
àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.
Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,
iṣẹ́ ọwọ́ mi,
láti fi ọláńlá mi hàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.