Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.

Isaiah 55:4 in English

Isaiah 55:4 · Berean Standard Bible

Behold, I have made him a witness to the nations, a leader and commander of the peoples.

Context

2Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn? Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu. 3Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi; gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè. Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ, ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi. 4Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn. 5Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ẹni Mímọ́ Israẹli nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.” 6Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.