Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

Isaiah 55:6 in English

Isaiah 55:6 · Berean Standard Bible

Seek the LORD while He may be found; call on Him while He is near.

Context

4Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn. 5Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ẹni Mímọ́ Israẹli nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.” 6Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. 7Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀. Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì. 8“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.