Isaiah 55:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà; òkè ńlá ńlá àti kéékèèké yóò bú sí orin níwájú yín àti gbogbo igi inú pápá yóò máa pàtẹ́wọ́.
Isaiah 55:12 in English
Isaiah 55:12 · Berean Standard Bible
You will indeed go out with joy and be led forth in peace; the mountains and hills will burst into song before you, and all the trees of the field will clap their hands.
Context
10Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín
ti wálẹ̀ láti ọ̀run
tí kì í sì padà sí ibẹ̀
láì bomirin ilẹ̀
kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi,
tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn
àti àkàrà fún ọ̀jẹun, 11bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá;
kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,
ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́,
yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ. 12Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀
a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà;
òkè ńlá ńlá àti kéékèèké
yóò bú sí orin níwájú yín
àti gbogbo igi inú pápá
yóò máa pàtẹ́wọ́. 13Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà,
àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ.
Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa,
fún àmì ayérayé,
tí a kì yóò lè parun.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.