Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.

Isaiah 55:11 in English

Isaiah 55:11 · Berean Standard Bible

so My word that proceeds from My mouth will not return to Me empty, but it will accomplish what I please, and it will prosper where I send it.

Context

9“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ. 10Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín ti wálẹ̀ láti ọ̀run tí kì í sì padà sí ibẹ̀ láì bomirin ilẹ̀ kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn àti àkàrà fún ọ̀jẹun, 11bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ. 12Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà; òkè ńlá ńlá àti kéékèèké yóò bú sí orin níwájú yín àti gbogbo igi inú pápá yóò máa pàtẹ́wọ́. 13Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà, àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ. Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa, fún àmì ayérayé, tí a kì yóò lè parun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.