Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí.

Isaiah 54:6 in English

Isaiah 54:6 · Berean Standard Bible

For the LORD has called you back, like a wife deserted and wounded in spirit, like the rejected wife of one’s youth,” says your God.

Context

4“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ, ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́. 5Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé. 6Olúwa yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí. 7“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá. 8Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,” ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.